Johanu 8:3
John 8:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín.
John 8:3 in English
John 8:3 · Berean Standard Bible
The scribes and Pharisees, however, brought to Him a woman caught in adultery. They made her stand before them
Context
1Jesu sì lọ sí orí òkè olifi. 2Ó sì tún padà wá sí tẹmpili ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gbogbo ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì jókòó, ó ń kọ́ wọn. 3Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín. 4Wọ́n sì wí fún un pé, “Olùkọ́, a mú obìnrin yìí nínú ìṣe panṣágà. 5Ǹjẹ́ nínú òfin, Mose pàṣẹ fún wa láti sọ irú àwọn obìnrin bẹ́ẹ̀ ní òkúta, ṣùgbọ́n ìwọ ha ti wí?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.