Johanu 19:23
John 19:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.
John 19:23 in English
John 19:23 · Berean Standard Bible
When the soldiers had crucified Jesus, they divided His garments into four parts, one for each soldier, with the tunic remaining. It was seamless, woven in one piece from top to bottom.
Context
21Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù,’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.” 22Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́. 23Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀. 24Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”
Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,
“Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”
Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe. 25Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.