Johanu 19:24
John 19:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.” Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé, “Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.” Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe.
John 19:24 in English
John 19:24 · Berean Standard Bible
So they said to one another, “Let us not tear it. Instead, let us cast lots to see who will get it.” This was to fulfill the Scripture: “They divided My garments among them, and cast lots for My clothing.”* So that is what the soldiers did.
Context
22Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́. 23Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀. 24Nítorí náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Ẹ má jẹ́ kí a fà á ya, ṣùgbọ́n kí a ṣẹ́ gègé nítorí rẹ̀.”
Ti ẹni tí yóò jẹ́: kí ìwé mímọ́ kí ó le ṣẹ, tí ó wí pé,
“Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn,
wọ́n sì ṣẹ́ gègé fún aṣọ ìlekè mi.”
Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ọmọ-ogun ṣe. 25Ìyá Jesu àti arábìnrin ìyá rẹ̀ Maria aya Kilopa, àti Maria Magdalene sì dúró níbi àgbélébùú, 26nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ-ẹ̀yìn náà dúró, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obìnrin, wo ọmọ rẹ!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.