Native Bible

John 19:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù,’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.”

John 19:21 in English

John 19:21 · Berean Standard Bible

So the chief priests of the Jews said to Pilate, “Do not write, ‘The King of the Jews,’ but only that He said, ‘I am the King of the Jews.’”

Context

19Pilatu sì kọ ìwé kan pẹ̀lú, ó sì fi lé e lórí àgbélébùú náà. Ohun tí a sì kọ ni, Jesu ti Nasareti Ọba àwọn Júù. 20Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni ó ka ìwé àkọlé yìí, nítorí ibi tí a gbé kan Jesu mọ́ àgbélébùú súnmọ́ etí ìlú, a sì kọ ọ́ ní èdè Heberu àti Latin, àti ti Giriki. 21Nítorí náà àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù wí fún Pilatu pé, “Má ṣe kọ, ‘Ọba àwọn Júù,’ ṣùgbọ́n pé ọkùnrin yìí wí pé, èmi ni ọba àwọn Júù.” 22Pilatu dáhùn pé, ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́. 23Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun, nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ àgbélébùú tán, wọ́n mú aṣọ rẹ̀, wọ́n sì pín wọn sí ipa mẹ́rin, apá kan fún ọmọ-ogun kọ̀ọ̀kan, àti ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà kò ní ojúràn-án, wọ́n hun ún láti òkè títí jálẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.