Johanu 15:3
John 15:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín.
John 15:3 in English
John 15:3 · Berean Standard Bible
You are already clean because of the word I have spoken to you.
Context
1“Èmi ni àjàrà tòótọ́, Baba mi sì ni olùṣọ́gbà. 2Gbogbo ẹ̀ka nínú mi tí kò bá so èso, òun a mú kúrò, gbogbo ẹ̀ka tí ó bá sì so èso, òun a wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí ó lè so èso sí i. 3Ẹ̀yin mọ́ nísinsin yìí nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín. 4Ẹ máa gbé inú mi, èmi ó sì máa gbé inú yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka kò ti lè so èso fún ara rẹ̀ bí kò ṣe pé ó ba ń gbé inú àjàrà, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ bá ń gbé inú mi. 5“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọ́pọ̀, nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.