Jeremiah 8:20
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìkórè ti rékọjá, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí, síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
Jeremiah 8:20 in English
Jeremiah 8:20 · Berean Standard Bible
“The harvest has passed, the summer has ended, but we have not been saved.”
Context
18Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi,
rẹ̀wẹ̀sì nínú mi. 19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi
láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:
“Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?
Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”
“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn,
pẹ̀lú àwọn òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?” 20“Ìkórè ti rékọjá,
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí,
síbẹ̀ a kò gbà wá là.” 21Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,
èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká. 22Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?
Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?
Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn
fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.