Jeremiah 6:7
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀, náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde. Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀; nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
Jeremiah 6:7 in English
Jeremiah 6:7 · Berean Standard Bible
As a well gushes its water, so she pours out her evil. Violence and destruction resound in her; sickness and wounds are ever before Me.
Context
5Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́
kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.” 6Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
nítorí pé ó kún fún ìninilára. 7Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,
náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.
Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;
nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi. 8Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀,
kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,
kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,
tí kò ní ní olùgbé.” 9Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli
ní tónítóní bí àjàrà;
na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i
gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.