Jeremiah 6:28
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.
Jeremiah 6:28 in English
Jeremiah 6:28 · Berean Standard Bible
All are hardened rebels, walking around as slanderers. They are bronze and iron; all of them are corrupt.
Context
26Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,
kí ẹ sì sùn nínú eérú,
ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún
gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo
nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá. 27“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́
irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù,
kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,
kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò. 28Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.
Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.
Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,
wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́. 29Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,
kí ó lè yọ́ òjé,
ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;
a kò si ya ènìyàn búburú kúrò. 30A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,
nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.