Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.

Jeremiah 6:26 in English

Jeremiah 6:26 · Berean Standard Bible

O daughter of my people, dress yourselves in sackcloth and roll in ashes. Mourn with bitter wailing, as you would for an only son, for suddenly the destroyer will come upon us.

Context

24Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí. 25Má ṣe jáde lọ sí orí pápá tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà, ìpayà sì wà níbi gbogbo. 26Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀, kí ẹ sì sùn nínú eérú, ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá. 27“Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́ irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí, kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò. 28Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn. Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì. Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin, wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.