Jeremiah 6:24
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa bí obìnrin tí ń rọbí.
Jeremiah 6:24 in English
Jeremiah 6:24 · Berean Standard Bible
We have heard the report; our hands hang limp. Anguish has gripped us, pain like that of a woman in labor.
Context
22Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,
a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde
láti òpin ayé wá. 23Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,
wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú.
Wọ́n ń hó bí omi Òkun,
bí wọ́n ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;
wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò jà ọ́ lógun,
ìwọ ọmọbìnrin Sioni.” 24Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa
bí obìnrin tí ń rọbí. 25Má ṣe jáde lọ sí orí pápá
tàbí kí o máa rìn ní àwọn ojú ọ̀nà,
nítorí ọ̀tá náà ní idà,
ìpayà sì wà níbi gbogbo. 26Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,
kí ẹ sì sùn nínú eérú,
ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún
gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo
nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.