Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadnessari o kó ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) láti Jerusalẹmu.

Jeremiah 52:29 in English

Jeremiah 52:29 · Berean Standard Bible

in Nebuchadnezzar’s eighteenth year, 832 people from Jerusalem;

Context

27Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati. Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. 28Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì. Ní ọdún keje ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda. 29Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadnessari o kó ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) láti Jerusalẹmu. 30Ní ọdún kẹtàlélógún àwọn Júù tí Nebusaradani kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín márùn-ún (745). Gbogbo ènìyàn tí ó kó lápapọ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀tàlélógún (4,600). 31Ní ọdún kẹtàdínlógójì ti Jehoiakini ọba Juda ni Efili-Merodaki di ọba Babeli. Ó gbé orí Jehoiakini ọba Juda sókè, ó sì tú sílẹ̀ nínú túbú ní ọjọ́ kẹẹdọ́gbọ̀n oṣù kejìlá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.