Jeremiah 52:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati. Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.
Jeremiah 52:27 in English
Jeremiah 52:27 · Berean Standard Bible
There at Riblah in the land of Hamath, the king of Babylon struck them down and put them to death. So Judah was taken into exile, away from its own land.
Context
25Nínú àwọn tí ó kù ní ilẹ̀ náà, ó mú ìwẹ̀fà kan, tí ó wà ní ìtọ́jú àwọn ológun, àti àwọn olùdámọ̀ràn ọba méje. Bákan náà, ó tún mu akọ̀wé olórí ogun tí ó wà ní ìtọ́jú títo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti ọgọ́ta nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ tí wọ́n rí ní ìlú náà. 26Nebusaradani, balógun ìṣọ́ kó gbogbo wọn, ó sì mú wọn tọ ọba Babeli wá ní Ribla. 27Ọba Babeli sì kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n ní Ribla ni ilẹ̀ Hamati.
Báyìí ni a mú Juda kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. 28Èyí ni iye àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì.
Ní ọdún keje ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mẹ́tàlélógún (3,023) ará Juda. 29Ní ọdún kejìdínlógún Nebukadnessari
o kó ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (832) láti Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.