Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́. Ẹ hu fun un! Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn.

Jeremiah 51:8 in English

Jeremiah 51:8 · Berean Standard Bible

Suddenly Babylon has fallen and been shattered. Wail for her; get her balm for her pain; perhaps she can be healed.

Context

6“Sá kúrò ní Babeli! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Má ṣe ṣègbé torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Àsìkò àti gbẹ̀san Olúwa ni èyí; yóò sán fún òun gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́. 7Ife wúrà ni Babeli ní ọwọ́ Olúwa; ó sọ gbogbo ayé di ọ̀mùtí. Gbogbo orílẹ̀-èdè mu ọtí rẹ̀, wọ́n sì ti ya òmùgọ̀ kalẹ̀. 8Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́. Ẹ hu fun un! Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ, bóyá yóò le wo ọ́ sàn. 9“ ‘À bá ti wo Babeli sàn, ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀, kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè, ó ga àní títí dé òfúrufú.’ 10“ ‘Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.