Jeremiah 51:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Olúwa ti dá wa láre, wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa Ọlọ́run wa ti ṣe.’
Jeremiah 51:10 in English
Jeremiah 51:10 · Berean Standard Bible
“The LORD has brought forth our vindication; come, let us tell in Zion what the LORD our God has accomplished.”
Context
8Babeli yóò ṣubú lójijì, yóò sì fọ́.
Ẹ hu fun un!
Ẹ mú ìkunra fún ìrora rẹ,
bóyá yóò le wo ọ́ sàn. 9“ ‘À bá ti wo Babeli sàn,
ṣùgbọ́n kò lè sàn, ẹ jẹ́ kí a fi sílẹ̀,
kí oníkálùkù lọ sí ilẹ̀ rẹ̀ torí ìdájọ́ rẹ̀ tó gòkè,
ó ga àní títí dé òfúrufú.’ 10“ ‘Olúwa ti dá wa láre,
wá jẹ́ kí a sọ ọ́ ní Sioni ohun tí Olúwa
Ọlọ́run wa ti ṣe.’ 11“Ṣe ọfà rẹ ní mímú,
mú àpáta!
Olúwa ti ru ọba Media sókè,
nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Babeli run.
Olúwa yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún tẹmpili rẹ̀. 12Gbé àsíá sókè sí odi Babeli!
Ẹ ṣe àwọn ọmọ-ogun gírí,
ẹ pín àwọn olùṣọ́ káàkiri,
ẹ ṣètò àwọn tí yóò sá pamọ́
Olúwa! Yóò gbé ète rẹ̀ jáde,
òfin rẹ̀ sí àwọn ará Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.