Jeremiah 51:47
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli; gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.
Jeremiah 51:47 in English
Jeremiah 51:47 · Berean Standard Bible
Therefore, behold, the days are coming when I will punish the idols of Babylon. Her entire land will suffer shame, and all her slain will lie fallen within her.
Context
45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀
ẹ̀yin ènìyàn mi!
Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!
Sá fún ìbínú ńlá Olúwa. 46Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú
tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí
a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;
àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,
òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá
ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì. 47Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan
nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli;
gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì
gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀. 48Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,
yóò sì kọrin lórí Babeli:
nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”
ni Olúwa wí. 49“Babiloni gbọdọ̀ ṣubú nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni Israẹli,
gẹ́gẹ́ bí àwọn ti a pa ní gbogbo ayé nítorí Babeli.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.