Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Olúwa.

Jeremiah 51:45 in English

Jeremiah 51:45 · Berean Standard Bible

Come out of her, My people!* Save your lives, each of you, from the fierce anger of the LORD.

Context

43Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro, ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò. 44Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó. 45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn mi! Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ! Sá fún ìbínú ńlá Olúwa. 46Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa; àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí, òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì. 47Nítorí ìgbà náà yóò wá dandan nígbà tí èmi yóò fi ìyà jẹ àwọn òrìṣà Babeli; gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ni a ó dójútì gbogbo àwọn tí a pa yóò sì ṣubú ní àárín rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.