Jeremiah 51:44
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì. Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́. Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó.
Jeremiah 51:44 in English
Jeremiah 51:44 · Berean Standard Bible
I will punish Bel in Babylon. I will make him spew out what he swallowed. The nations will no longer stream to him; even the wall of Babylon will fall.
Context
42Òkun yóò ru borí Babeli,
gbogbo rírú rẹ̀ yóò borí Babeli. 43Àwọn ìlú rẹ̀ yóò di ahoro,
ilẹ̀ tí ó gbẹ, ilẹ̀ tí ènìyàn
kò gbé tí ènìyàn kò sì rin ìrìnàjò. 44Èmi yóò fi ìyà jẹ Beli ti Babeli
àti pé èmi yóò jẹ́ kí ó pọ gbogbo àwọn ohun tí ó gbé mì.
Àwọn orílẹ̀-èdè kì yóò jùmọ̀ sàn lọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ mọ́.
Ní òótọ́ odi Babeli yóò sì wó. 45“Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀
ẹ̀yin ènìyàn mi!
Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ!
Sá fún ìbínú ńlá Olúwa. 46Má ṣe jẹ́ kí ọkàn rẹ dàrú
tàbí kí o bẹ̀rù nígbà tí
a bá gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ wa;
àhesọ ọ̀rọ̀ kan wá ní ọdún yìí,
òmíràn ní ọdún mìíràn àhesọ ọ̀rọ̀ ni ti ìwà ipá
ní ilẹ̀ náà àti tí aláṣẹ kan sí aláṣẹ kejì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.