Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀, jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀. Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí; pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀.

Jeremiah 51:3 in English

Jeremiah 51:3 · Berean Standard Bible

Do not let the archer bend his bow or put on his armor. Do not spare her young men; devote all her army to destruction!*

Context

1Ohùn ti Olúwa wí nìyìí: “Wò ó èmi yóò ru afẹ́fẹ́ apanirun sókè sí Babeli àti àwọn ènìyàn Lebikamai, 2Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Babeli láti fẹ́ ẹ, tí yóò sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di òfo; wọn yóò takò ó ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀. 3Má ṣe jẹ́ kí tafàtafà yọ ọfà rẹ̀, jáde tàbí kí ó di ìhámọ́ra rẹ̀. Má ṣe dá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí; pátápátá ni kí o pa àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 4Gbogbo wọn ni yóò ṣubú ní Babeli, tí wọn yóò sì fi ara pa yánnayànna ní òpópónà. 5Nítorí pé Juda àti Israẹli ni Ọlọ́run wọn tí í ṣe Olúwa àwọn ọmọ-ogun, kò gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn kún fún kìkì ẹ̀bi níwájú ẹni mímọ́ Israẹli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.