Jeremiah 50:43
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Jeremiah 50:43 in English
Jeremiah 50:43 · Berean Standard Bible
The king of Babylon has heard the report, and his hands hang limp. Anguish has gripped him, pain like that of a woman in labor.
Context
41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá;
orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń
gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé. 42Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun,
wọ́n burú wọn kò sì ní àánú.
Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ.
Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli. 43Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
ọwọ́ wọn sì rọ,
ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí. 44Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani
sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?” 45Nítorí náà, gbọ́ ohun tí
Olúwa sọ nípa Babeli,
ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Babeli:
n ó sì pa agbo ẹran wọn run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.