Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli.

Jeremiah 50:42 in English

Jeremiah 50:42 · Berean Standard Bible

They grasp the bow and spear;* they are cruel and merciless. Their voice roars like the sea, and they ride upon horses, lined up like men in formation against you, O Daughter of Babylon.

Context

40Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti gba ìjọba Sodomu àti Gomorra pẹ̀lú àwọn ìlú agbègbè wọn,” ni Olúwa wí, “torí náà kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé ibẹ̀; ènìyàn ki yóò gbé nínú rè. 41“Wò ó! Ọ̀wọ́ ọmọ-ogun láti ìhà àríwá; orílẹ̀-èdè ńlá àti àwọn ọba púpọ̀ ni à ń gbé dìde láti òpin ilẹ̀ ayé. 42Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n n ké bí i rírú omi bí wọ́n ti ṣe ń gun ẹṣin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Babeli. 43Ọba Babeli ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn, ọwọ́ wọn sì rọ, ìrora mú wọn bí obìnrin tí ó ń rọbí. 44Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá, Èmi ó lé Babeli kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀? Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí? Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.