Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

Jeremiah 5:2 in English

Jeremiah 5:2 · Berean Standard Bible

Although they say, ‘As surely as the LORD lives,’ they are swearing falsely.”

Context

1“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu, wò yíká, kí o sì mọ̀, kí o sì wá kiri. Bí o bá le è rí ẹnìkan, tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo, n ó dáríjì ìlú yìí. 2Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’ síbẹ̀ wọ́n búra èké.” 3Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́? Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n; ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà. 4Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.