Jeremiah 5:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí; wọn jẹ́ aṣiwèrè, nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa, àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
Jeremiah 5:4 in English
Jeremiah 5:4 · Berean Standard Bible
Then I said, “They are only the poor; they have played the fool, for they do not know the way of the LORD, the justice of their God.
Context
2Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’
síbẹ̀ wọ́n búra èké.” 3Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́?
Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n;
ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,
wọ́n sì kọ̀ láti yípadà. 4Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí;
wọn jẹ́ aṣiwèrè,
nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,
àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́. 5Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,
n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;
ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa
àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,
wọ́n sì ti já ìdè. 6Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,
ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run,
ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín
ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,
ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.