Jeremiah 49:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn, a ó gbọ́ igbe wọn ní Òkun pupa.
Jeremiah 49:21 in English
Jeremiah 49:21 · Berean Standard Bible
At the sound of their fall the earth will quake; their cry will resound to the Red Sea.*
Context
19“Bí i kìnnìún ni òun ó gòkè wá láti igbó Jordani sí orí ilẹ̀ ọlọ́ràá,
Èmi ó lé Edomu kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá.
Ta ni àyànfẹ́ náà tí èmi ó yàn sórí rẹ̀?
Ta ló dàbí mi, ta ni ó sì pé mi ṣe ẹlẹ́rìí?
Ta ni olùṣọ́-àgùntàn náà tí yóò le dúró níwájú mi?” 20Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí
Olúwa ní fún Edomu,
ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Temani.
Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde;
pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn. 21Ilẹ̀ yóò mì tìtì nípa ariwo ìṣubú wọn,
a ó gbọ́ igbe wọn
ní Òkun pupa. 22Wò ó! Ẹyẹ idì yóò gòkè fò wálẹ̀,
yóò tẹ ìyẹ́ rẹ̀ lórí Bosra.
Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ajagun
Edomu yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ń rọbí. 23Nípa Damasku.
“Inú Hamati àti Arpadi bàjẹ́ nítorí wọ́n gbọ́ ìròyìn búburú, ìjayà dé bá wọn,
wọ́n sì dààmú bí omi Òkun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.