Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu. Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò.

Jeremiah 48:28 in English

Jeremiah 48:28 · Berean Standard Bible

Abandon the towns and settle among the rocks, O dwellers of Moab! Be like a dove that nests at the mouth of a cave.

Context

26“Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa, jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn. 27Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? 28Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu. Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò. 29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu: àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀. 30Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí, “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.