Jeremiah 48:27
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
Jeremiah 48:27 in English
Jeremiah 48:27 · Berean Standard Bible
Was not Israel your object of ridicule? Was he ever found among thieves? For whenever you speak of him you shake your head.
Context
25A gé ìwo Moabu kúrò,
apá rẹ̀ dá,”
ni Olúwa wí. 26“Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí
nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa,
jẹ́ kí Moabu lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀,
kí ó di ẹni ẹ̀gàn. 27Ǹjẹ́ Israẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ?
Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè
tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́
nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? 28Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta,
ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú Moabu.
Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀
sí ẹnu ihò. 29“A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu:
àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀
àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.