Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.

Jeremiah 46:4 in English

Jeremiah 46:4 · Berean Standard Bible

Harness the horses; mount the steeds; take your positions with helmets on! Polish your spears; put on armor!

Context

2Nípa Ejibiti. Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: 3“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà! 4Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin. 5Kí ni nǹkan tí mo tún rí? Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun. Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,” ni Olúwa wí. 6“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà. Ní àríwá ní ibi odò Eufurate wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.