Jeremiah 46:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
Jeremiah 46:3 in English
Jeremiah 46:3 · Berean Standard Bible
“Deploy your shields, small and large; advance for battle!
Context
1Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè. 2Nípa Ejibiti.
Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda: 3“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,
kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà! 4Ẹ di ẹṣin ní gàárì,
kí ẹ sì gùn ún.
Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ
pẹ̀lú àṣíborí yín!
Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,
kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin. 5Kí ni nǹkan tí mo tún rí?
Wọ́n bẹ̀rù,
wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,
wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.
Wọ́n sá,
wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,
ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.