Jeremiah 46:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà. Ní àríwá ní ibi odò Eufurate wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.
Jeremiah 46:6 in English
Jeremiah 46:6 · Berean Standard Bible
“The swift cannot flee, and the warrior cannot escape! In the north by the River Euphrates they stumble and fall.
Context
4Ẹ di ẹṣin ní gàárì,
kí ẹ sì gùn ún.
Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ
pẹ̀lú àṣíborí yín!
Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,
kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin. 5Kí ni nǹkan tí mo tún rí?
Wọ́n bẹ̀rù,
wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,
wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.
Wọ́n sá,
wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,
ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”
ni Olúwa wí. 6“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,
tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.
Ní àríwá ní ibi odò Eufurate
wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. 7“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,
tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì? 8Ejibiti dìde bí odò náà,
bí omi odò tí ń ru.
Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’
Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.