Jeremiah 46:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú? Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
Jeremiah 46:15 in English
Jeremiah 46:15 · Berean Standard Bible
Why have your warriors been laid low? They cannot stand, for the LORD has thrust them down.
Context
13Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti: 14“Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,
sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:
‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,
nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’ 15Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?
Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú. 16Wọn yóò máa ṣubú léraléra
wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.
Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà
sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,
kúrò níbi idà àwọn aninilára.’ 17Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,
‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,
ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.