Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’

Jeremiah 46:16 in English

Jeremiah 46:16 · Berean Standard Bible

They continue to stumble; indeed, they have fallen over one another. They say, ‘Get up! Let us return to our people and to the land of our birth, away from the sword of the oppressor.’

Context

14“Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli, sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi: ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’ 15Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú? Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú. 16Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’ 17Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé, ‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa, ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’ 18“Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.