Jeremiah 46:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:
Jeremiah 46:13 in English
Jeremiah 46:13 · Berean Standard Bible
This is the word that the LORD spoke to Jeremiah the prophet about the coming of Nebuchadnezzar king of Babylon to strike the land of Egypt:
Context
11“Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,
ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.
Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,
kì yóò sí ìwòsàn fún ọ. 12Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,
igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.
Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,
àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.” 13Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti: 14“Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,
sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:
‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,
nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’ 15Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?
Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.