Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”

Jeremiah 42:4 in English

Jeremiah 42:4 · Berean Standard Bible

“I have heard you,” replied Jeremiah the prophet. “I will surely pray to the LORD your God as you request, and I will tell you everything that the LORD answers; I will not withhold a word from you.”

Context

2Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù. 3Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.” 4Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.” 5Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremiah wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrín wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa. 6Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, èyí tí àwa ń rán ọ sí, kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.