Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù.

Jeremiah 42:2 in English

Jeremiah 42:2 · Berean Standard Bible

Jeremiah the prophet and said, “May our petition come before you; pray to the LORD your God on behalf of this entire remnant. For few of us remain of the many, as you can see with your own eyes.

Context

1Nígbà náà ní gbogbo àwọn olórí ogun àti Johanani ọmọkùnrin Karea àti Jesaniah ọmọkùnrin Hoṣaiah àti kékeré títí dé orí ẹni ńlá wá. 2Sí ọ̀dọ̀ Jeremiah wòlíì náà, wọ́n sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa, kí o sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ fún gbogbo ìyókù yìí. Nítorí gẹ́gẹ́ bi ìwọ ṣe rí i nísinsin yìí pé a pọ̀ níye nígbà kan rí; ṣùgbọ́n báyìí àwa díẹ̀ la ṣẹ́kù. 3Gbàdúrà pé kí Olúwa Ọlọ́run rẹ sọ ibi tí àwa yóò lọ fún wa àti ohun tí àwa yóò ṣe.” 4Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.