Jeremiah 42:6
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, èyí tí àwa ń rán ọ sí, kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
Jeremiah 42:6 in English
Jeremiah 42:6 · Berean Standard Bible
Whether it is pleasant or unpleasant, we will obey the voice of the LORD our God to whom we are sending you, so that it may go well with us, for we will obey the voice of the LORD our God!”
Context
4Wòlíì Jeremiah sì dáhùn wí pé, “Mo ti gbọ́. Èmi yóò gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run yín gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ṣe béèrè. Èmi yóò sọ gbogbo ohun tí Olúwa bá sọ fún un yín, ń kò sì ní fi ohunkóhun pamọ́ fún un yín.” 5Nígbà náà ni wọ́n sọ fún Jeremiah wí pé, “Kí Olúwa ṣe ẹlẹ́rìí òtítọ́ àti òdodo láàrín wa, bí àwa kò bá ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá rán ọ láti sọ fún wa. 6Ìbá à ṣe rere, ìbá à ṣe búburú, àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, èyí tí àwa ń rán ọ sí, kí ó ba à lè dára fún wa. Nítorí pé àwa yóò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.” 7Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá, 8O sì pe Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni ńlá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.