Jeremiah 42:12
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’
Jeremiah 42:12 in English
Jeremiah 42:12 · Berean Standard Bible
And I will show you compassion, and he will have compassion on you and restore you to your own land.’
Context
10Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín. 11Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀. 12Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’ 13“Ṣùgbọ́n sá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín. 14Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Ejibiti; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.