Jeremiah 42:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín.
Jeremiah 42:10 in English
Jeremiah 42:10 · Berean Standard Bible
‘If you will indeed stay in this land, then I will build you up and not tear you down; I will plant you and not uproot you, for I will relent of the disaster I have brought upon you.
Context
8O sì pe Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀; àti gbogbo àwọn ènìyàn láti orí ẹni tí ó kéré dé orí ẹni ńlá. 9Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: ‘Èyí ni ẹni tí ẹ̀yin ti rán láti gbé ẹ̀bẹ̀ yín lọ síwájú mi. 10Bí ẹ̀yin bá gbé ní ilẹ̀ yìí, èmi yóò gbé e yín ró, n kò sí ní fà yín lulẹ̀, èmi yóò gbìn yín, n kì yóò fà yín tu nítorí wí pé èmi yí ọkàn padà ní ti ibi tí mo ti ṣe sí i yín. 11Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọba Babeli tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù, báyìí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀ ni Olúwa wí; nítorí tí èmi wà pẹ̀lú yín láti pa yín mọ́ àti láti gbà yín ní ọwọ́ rẹ̀. 12Èmi yóò fi àánú hàn sí i yín, kí ó lè ṣàánú fún un yín, kí ó sì mú un yín padà sí ilẹ̀ yín.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.