Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

Jeremiah 35:11 in English

Jeremiah 35:11 · Berean Standard Bible

So when Nebuchadnezzar king of Babylon marched into the land, we said: ‘Come, let us go into Jerusalem to escape the armies of the Chaldeans * and the Arameans.’ So we have remained in Jerusalem.”

Context

9Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.” 12Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13“Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.