Jeremiah 35:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn.
Jeremiah 35:9 in English
Jeremiah 35:9 · Berean Standard Bible
Nor have we built houses in which to live, and we have not owned any vineyards or fields or crops.
Context
7Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’ 8Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa. 9Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.