Jeremiah 35:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.
Jeremiah 35:13 in English
Jeremiah 35:13 · Berean Standard Bible
“This is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: Go and tell the men of Judah and the residents of Jerusalem: ‘Will you not accept discipline and obey My words?’ declares the LORD.
Context
11Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.” 12Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13“Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 14‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 15Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.