Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:

Jeremiah 32:16 in English

Jeremiah 32:16 · Berean Standard Bible

After I had given the deed of purchase to Baruch son of Neriah, I prayed to the LORD:

Context

14èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀. 15Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí. 16“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé: 17“Háà! Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. 18O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.