Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ.

Jeremiah 32:18 in English

Jeremiah 32:18 · Berean Standard Bible

You show loving devotion to thousands but lay the iniquity of the fathers into the laps * of their children after them, O great and mighty God whose name is the LORD of Hosts,

Context

16“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé: 17“Háà! Olúwa Olódùmarè, ìwọ tí o dá ọ̀run àti ayé pẹ̀lú títóbi agbára rẹ àti gbogbo ọ̀rọ̀ apá rẹ. Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ láti ṣe. 18O fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n o gbé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba lé àwọn ọmọ lẹ́yìn wọn. Ọlọ́run títóbi àti alágbára, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ. 19Títóbi ni ìgbìmọ̀, àti alágbára ní í ṣe, ojú rẹ̀ ṣì sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn; láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso iṣẹ́ rẹ̀. 20O ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá ní Ejibiti. O sì ń ṣe é títí di òní ní Israẹli àti lára ọmọ ènìyàn tí ó sì ti gba òkìkí tí ó jẹ́ tìrẹ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.