Jeremiah 32:14
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.
Jeremiah 32:14 in English
Jeremiah 32:14 · Berean Standard Bible
“This is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: Take these deeds—both the sealed copy and the open copy of the deed of purchase—and put them in a clay jar to preserve them for a long time.
Context
12Èmi sì fi èyí fún Baruku, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, ní ojú Hanameli, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú. 13“Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Baruku pé, 14èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀. 15Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí. 16“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.