Jeremiah 31:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn; ‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ, yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’
Jeremiah 31:10 in English
Jeremiah 31:10 · Berean Standard Bible
Hear, O nations, the word of the LORD, and proclaim it in distant coastlands: “The One who scattered Israel will gather them and keep them as a shepherd keeps his flock.
Context
8Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá;
èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé.
Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ,
aboyún àti obìnrin tí ń rọbí,
ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá. 9Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún,
wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà.
Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi;
ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú,
nítorí èmi ni baba Israẹli,
Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi. 10“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
ẹ kéde rẹ̀ ní erékùṣù jíjìn;
‘Ẹni tí ó bá tú Israẹli ká yóò kójọ,
yóò sì ṣọ́ agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn.’ 11Nítorí Olúwa ti tú Jakọbu sílẹ̀, o sì rà á padà
ní ọwọ́ àwọn tí ó lágbára jù ú lọ. 12Wọn yóò wá, wọn ó sì hó ìhó ayọ̀ lórí òkè Sioni;
wọn yóò yọ ayọ̀ níbi oore Olúwa.
Àlìkámà ni, ọtí wáìnì tuntun àti òróró
ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọ̀dọ́ ọ̀wọ́ ẹran.
Wọn ó dàbí ọgbà àjàrà tí a bomirin,
ìkorò kò ní bá wọn mọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.