Jeremiah 30:9
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
Jeremiah 30:9 in English
Jeremiah 30:9 · Berean Standard Bible
Instead, they will serve the LORD their God and David their king, whom I will raise up for them.
Context
7Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!
Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,
Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu
ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà. 8“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,
Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.
Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́. 9Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn
àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,
ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn. 10“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’
ni Olúwa wí.
‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,
àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.
Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,
kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́. 11Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’
ni Olúwa wí.
‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,
síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.
Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;
Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.