Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.

Jeremiah 30:10 in English

Jeremiah 30:10 · Berean Standard Bible

As for you, O Jacob My servant, do not be afraid, declares the LORD, and do not be dismayed, O Israel. For I will surely save you out of a distant place, your descendants from the land of their captivity! Jacob will return to quiet and ease, with no one to make him afraid.

Context

8“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́. 9Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn. 10“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́. 11Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’ 12“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.