Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

Jeremiah 3:18 in English

Jeremiah 3:18 · Berean Standard Bible

In those days the house of Judah will walk with the house of Israel, and they will come together from the land of the north to the land that I gave to your fathers as an inheritance.

Context

16Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́. 17Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́. 18Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní. 19“Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn. 20Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,” ni Olúwa wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.