Jeremiah 25:35
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran.
Jeremiah 25:35 in English
Jeremiah 25:35 · Berean Standard Bible
Flight will evade the shepherds, and escape will elude the leaders of the flock.
Context
33Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀. 34Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn,
ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran.
Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé,
ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye. 35Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ
kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran. 36Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn,
àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran;
nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run. 37Ibùgbé àlàáfíà yóò di ahoro,
nítorí ìbínú ńlá Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.