Jeremiah 25:34
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn, ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran. Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye.
Jeremiah 25:34 in English
Jeremiah 25:34 · Berean Standard Bible
Wail, you shepherds, and cry out; roll in the dust, you leaders of the flock. For the days of your slaughter have come; you will fall and be shattered like fine pottery.*
Context
32Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Wò ó! Ibi ń tànkálẹ̀ láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn;
ìjì ńlá yóò sì ru sókè láti òpin ayé.” 33Nígbà náà, àwọn tí Olúwa ti pa yóò wà ní ibi gbogbo, láti ìpẹ̀kun kan sí òmíràn. A kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọ tàbí sin wọ́n; ṣùgbọ́n wọn yóò dàbí ààtàn lórí ilẹ̀. 34Ké, kí ẹ sì pohùnréré ẹkún ẹ̀yin olùṣọ́-àgùntàn,
ẹ yí nínú eruku, ẹ̀yin olùdarí agbo ẹran.
Nítorí pé ọjọ́ àti pa yín ti dé,
ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun èlò iyebíye. 35Àwọn olùṣọ́-àgùntàn kì yóò rí ibi sálọ
kì yóò sì ṣí àsálà fún olórí agbo ẹran. 36Gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn,
àti ìpohùnréré ẹkún àwọn olórí agbo ẹran;
nítorí pé Olúwa ń pa pápá oko tútù wọn run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.