Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.

Jeremiah 23:5 in English

Jeremiah 23:5 · Berean Standard Bible

Behold, the days are coming, declares the LORD, when I will raise up for David * a righteous Branch, and He will reign wisely as King and will administer justice and righteousness in the land.

Context

3“Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. 4Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí. 5“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi, ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà. 6Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu. Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa. 7Nítorí náà, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí ènìyàn kì yóò tún wí pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.