Jeremiah 23:3
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i.
Jeremiah 23:3 in English
Jeremiah 23:3 · Berean Standard Bible
Then I Myself will gather the remnant of My flock from all the lands to which I have banished them, and I will return them to their pasture, where they will be fruitful and multiply.
Context
1“Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí. 2Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí. 3“Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. 4Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí. 5“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,
ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n
tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.